Exodus 35:4-9

Ohun èlò fun Àgọ́

4 aMose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: 5Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti:

“wúrà, fàdákà àti idẹ;
6aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára;
àti irun ewúrẹ́;
7awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù;
odò igi kasia;
8òróró olifi fún títan iná;
olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;
9òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.
Copyright information for YorBMYO